2 Tímótíù 4 BMY

1 Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kírísítì Jésù, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀.

2 Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsinmi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bániwí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo.

3 Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó oluko jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kùfẹ́ ara wọn.

4 Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.

5 Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́nju, ṣe iṣẹ́ ẹ̀fáńjẹ́lísítì, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.

6 Nitorí à ń fí mi rúbọ nisínsinyìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etíle.

7 Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́;

8 Láti ìsinsinyìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàjọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.

Àwọn Àkíyèsí Ti Ara Ẹni.

9 Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá.

10 Nítorí Démà ti kọ̀ mí sílẹ̀, nitorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalóníkà; Kírésíkénì sí Gálátíà, Títù sí Dalimátíà.

11 Lúùkù nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Máàkù wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́-ìránṣẹ́.

12 Mo rán Tíkíkù ní iṣẹ lọ sí Éfésù.

13 Aṣọ òtútù tí mọ fi sílẹ̀ ní Tíróà lọ́dọ̀ Kárípù, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mu un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.

14 Alekisáńdérù alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀:

15 Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀.

16 Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn.

17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nipasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnìún náà.

18 Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ bubúrú gbogbo, yóò sì gbà mí dé inú ìjọba rẹ̀; ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. (Àmín).

Àwọn Ìkíni Ìkẹ́yìn

19 Kí Parísíkà àti Àkúílà, àti ilé Onésífórù.

20 Érásítù wà ní Kọ́ríntí: ṣùgbọ́n mo fi Tírófímù sílẹ̀ ni Mílétù nínú àìsàn.

21 Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù. Éúbúlù kí ọ, àti Páúdánì, àti Línù, Kíláúdíà, àti gbogbo àwọn ará-kùnrin.

22 Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín. (Àmín).

orí

1 2 3 4