15 Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò níláti tijú, tí ó ń pin ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ
16 Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí ti wọn máa ṣíwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run.
17 Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Híménéù àti Fílétù wà;
18 Àwọn ẹni tí ó ti sìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú.
19 Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúró nínú àìṣòdodo.”
20 Ṣùgbọ́n nínú ilé nla, kì í ṣe kìkì ohun-èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá.
21 Bí ẹnìkẹni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun-èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.