21 Bí ẹnìkẹni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun-èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.
22 Máa sá fún ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ èwe: sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá.
23 Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní èkọ́ nínú ni kí a kọ̀, bí a ti mọ̀ pe wọn a máa dá ìjà sílẹ̀.
24 Ìránsẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, onísùúrù.
25 Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrèti pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtìtọ́,
26 wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdèkùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.