1 Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé.
2 Nitori àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀-búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́.
3 Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlè-dáríjí-ni, abanijẹ́, aláìlè-kó-rawọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere,
4 oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ.
5 Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwá-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.