5 nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́.
6 Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábàápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ̀ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọ-ingbọ-in, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kírísítì wá.
7 Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lara.
8 Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ninú Kírísítì mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ,
9 ṣíbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, arúgbó, àti nísinsìnyìí òǹdè Jésù Kírísítì.
10 Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Ónísímu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè.
11 Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.