8 Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jésù Kírísítì.
9 Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti ṣíwájú síi nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,
10 kí ẹ̀yin kí ó lè dà ohun tí ó dára jùlọ yàtọ̀ mọ̀, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ọjọ́ Kírísítì,
11 tí ẹ sì kún fún èso òdodo tí ó ti ọ́dọ̀ Jésù Kírísítì wá—fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.
12 Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ẹlẹ̀ sí mi já sí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìyìnrere.
13 Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangban sí gbogbo àwọn ẹ̀sọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kírísítì.
14 Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni ẹ ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run síi pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.