1 Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú Bánábà, mo sì mú Títù lọ pẹ̀lú mi.
2 Mo gòkè lọ ní ìbámu ìfihàn, mo gbé ìyìn rere náà tí mo ń wàásù láàrin àwọn aláìkọlà kalẹ̀ níwájú wọn. Ṣùgbọ́n mo se èyí ní ìkọ̀kọ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ olùdarí, ni ẹ̀rù pé mo ń sáré tàbí mo tí sáré ìje mi lásán.
3 Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Títù tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Gíríkì láti kọlà.
4 Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárin wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kírísítì Jésù, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè.