Gálátíà 3 BMY

Igbàgbọ́ Tàbí Ìwòfífí Òfin

1 Ẹ̀yin aláìnírònú ará Gálátíà! ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jésù Kírísítì hàn gbangba láàrin yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú.

2 Kìkì èyí ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ yín: Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mi bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́?

3 Báyìí ni ẹ̀yin ṣe gọ̀ tó bí? Lẹyin tí ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa tí Ẹ̀mí, a há ṣe yín pé nísinsìnyìí nípa tí ara?

4 Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítoótọ́ lásán ni.

5 Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́-ìyanu láàrin yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ sí ohun tí ẹ gbọ́?

6 Gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí fún un ní òdodo.”

7 Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Ábúráhámù.

8 Bí ìwé-mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìyìn rere ṣáájú fún Ábúráhámù, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”

9 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkúnfún pẹ̀lú Ábúráhámù olódodo.

10 Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n.

11 Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnìkẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.”

12 Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n “Ẹnikẹ́ni tí ń se wọn yóò yè nípaṣẹ̀ wọn.”

13 Kírísítì ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.”

14 Kí ìbùkún Ábúráhámù ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kírísítì Jésù; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.

Òfin Àti Ìlérí

15 Ará, èmi ń ṣọ̀rọ̀ bí ènìyàn: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé májẹ̀mú ènìyàn ni, ṣùgbọ́n bí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́.

16 Ǹjẹ́ fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Òun kò ṣe wí pé, “Àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kírísítì.

17 Èyí tí mò ń wí ni pé: Májẹ̀mu tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣáájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, tí à bá fi mú ìlérí náà di aláìlágbára.

18 Nítorí bí ìjogún náà bá ṣe ti òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Ábúráhámù nípa ìlérí.

19 Ǹjẹ́ kí há ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipaṣẹ̀ àwọn áńgẹ́lì lànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá.

20 Ǹjẹ́ alárinà láàrin ẹgbẹ́ tí ó ju ọ̀kan ṣoṣo lọ; ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.

21 Nítorí náà òfín ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà.

22 Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ti sé gbogbo nǹkan mọ́ sábẹ́ ẹṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23 Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fi hàn.

24 Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùkọ́ni láti múni wá sọ́dọ̀ Kírísítì, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́.

25 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùkọ́ni mọ́.

Ọmọ Ọlọ́run

26 Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.

27 Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti baptisti sínú Kírísítì ti gbé Kírísítì wọ̀.

28 Kò le sí Júù tàbí Gíríkì, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí ọbìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kírísítì Jésù.

29 Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kírísítì, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Ábúráhámù, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

orí

1 2 3 4 5 6