Gálátíà 2:11-17 BMY

11 Ṣùgbọ́n nígbà tí Pétérù wá sí Ańtíókù, mo ta kò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ ẹni tí à bá báwí.

12 Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fà sẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà.

13 Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lati jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Bánábà lọnà.

14 Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédéé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìyìn rere, mo wí fún Pétérù níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn aláìkọlà, è é ṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn aláìkọlà láti máa rìn bí àwọn Júù?

15 “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’

16 Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, àní àwa pẹ̀lú gbà Jésù Kírísítì gbọ́, kí a báa lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kírísítì, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kírísítì, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ́lú jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kírísítì ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì!