18 Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fí ara mi hàn bí arúfin.
19 Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láàyè sí Ọlọ́run.
20 A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kírísítì, èmí kò sì wà láàyè mó, ṣùgbọ́n Kírísítì ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láàyè nínú ara, mo wà láàyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkararẹ̀ fún mi.
21 Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apákan: nítorí pé bí a bá le ti pasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kírísítì kú lásán.”