8 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti sìnrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ẹ̀dá.
9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a ṣá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, è é ha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti alágbe ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá sìnrú?
10 Ẹ̀yin ń kíyèsí ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún.
11 Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.
12 Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi: nítorí èmi dà bí ẹ̀yin: èyin kò ṣe mí ní ibi kan.
13 Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́.
14 Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, àní bí Kírísítì Jésù.