22 Ṣùgbọ́n èèso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,
23 Ìwà-tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí,
24 Àwọn tí í ṣe ti Kírísítì Jésù ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.
25 Bí àwa bá wà láàyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí.
26 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣògo-asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa.