3 Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbésè láti pa gbogbo òfin mọ́.
4 A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kírísítì, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́.
5 Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo.
6 Nítorí nínú Kírísítì Jésù ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
7 Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára; ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ran sí òtítọ́?
8 Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá.
9 Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú.