1 Ará, bí a tilẹ̀ mú ẹnìkan nínú ẹ̀sẹ̀ kan, kí ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù; kí ìwọ tìkárarẹ̀ máa kíyèsára, kí a má baà dán ìwọ náà wò pẹ̀lú.
2 Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kírísítì ṣẹ.
3 Nítorí bí ènìyàn kan bá ń ro ara rẹ̀ sí ẹnìkan, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ.
4 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀.
5 Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀.