15 Nítorí pé nínú Kírísítì Jésù ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun.
16 Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run.
17 Láti isinsínyìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́; nítorí èmi ń ru àpá Jésù Olúwa kiri ní ara mi.
18 Ará, oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.