14 Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, ìdàríjì ẹ̀sẹ̀.
15 Kírísítì ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.
16 Nítorì nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un.
17 Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ sọ̀kan.
18 Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí Òun lè ní ipo tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun.
19 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun lè máa gbé nínú rẹ̀.
20 Àti nípaṣẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ lọ́rùn, nípa mímú àlàáfíà wá nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélèbùú.