Kólósè 2 BMY

1 Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodékíà àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí.

2 Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ lè ní ìjìnlẹ̀ ìrírí ìmọ́ Kírísítì pẹ̀lú òye àti ìmọ̀ tó dájú ṣáká. Nítorí nísinsinyìí, Ọlọ́run ti fi àṣírí ètò hàn. Ìjìnlẹ̀ àṣírí ètò náà ni Kírísítì fúnrarẹ̀.

3 Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìsùra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí.

4 Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma baà fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín sìnà.

5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsí ètò yín àti bí ìdúró sinsin yín nínú Kírísítì ti rí.

Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Òfin Ènìyàn Nípa Ààyè Pẹ̀lú Kírísítì

6 Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jésù Kírísítì gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀.

7 Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé e yín ró nínú rẹ̀, ẹ máa se alágbára nínú ìgbàgbọ́, bí a ti ṣe kọ́ ọ yín, àti kí ẹ sì máa ṣàn bí omi pẹ̀lú ọpẹ́.

8 Ẹ máa kiyesii pé ẹnikẹ́ni kò fi ìmọ̀ àti ẹtan asan ko yín ní ìgbèkùn, èyí tí ó jẹmọ́ ìtàn ènìyàn bi ìpilẹ̀sẹ ẹ̀kọ́ ayé láìse ohun tí Kírísítì ti wí.

9 Nítorí nínú Kírísítì ni àti rí ẹ̀kún ìwà Ọlọ́run ní ipò ara,

10 ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kírísítì, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.

11 Nínú ẹni tí a kò fí ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní Ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kírísítì.

12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.

13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí o ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ni, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín;

14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn-án a mọ àgbélébùú;

15 Ó sì ti já àwọn aláṣẹ àìrí àti àwọn alágbára, ó ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn nínú rẹ̀.

16 Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àṣẹ, tàbí oṣù titun, àtì ọjọ́ ìsinmi:

17 Àwọn tí í ṣe òjìjí ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ti Kírísítì ni ara.

18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn ańgẹ́lì lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nipa èrò ti ọkan ara rẹ̀.

19 Tí kò sì di orí nì kú ṣinṣin, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ́kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.

20 Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kírísítì kúrò nínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin ń tẹ́ríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé,

21 Má ṣe dìímú, má se tọ́ ọ wò, má ṣe fọwọbàá,

22 Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn?

23 Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, ni àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọn-ara-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè hàn nínú fún ìfẹ́kúfẹ ara.

orí

1 2 3 4