12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.
13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí o ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ni, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín;
14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn-án a mọ àgbélébùú;
15 Ó sì ti já àwọn aláṣẹ àìrí àti àwọn alágbára, ó ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn nínú rẹ̀.
16 Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àṣẹ, tàbí oṣù titun, àtì ọjọ́ ìsinmi:
17 Àwọn tí í ṣe òjìjí ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ti Kírísítì ni ara.
18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn ańgẹ́lì lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nipa èrò ti ọkan ara rẹ̀.