18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn ańgẹ́lì lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nipa èrò ti ọkan ara rẹ̀.
19 Tí kò sì di orí nì kú ṣinṣin, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ́kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.
20 Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kírísítì kúrò nínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin ń tẹ́ríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé,
21 Má ṣe dìímú, má se tọ́ ọ wò, má ṣe fọwọbàá,
22 Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn?
23 Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, ni àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọn-ara-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè hàn nínú fún ìfẹ́kúfẹ ara.