6 Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jésù Kírísítì gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀.
7 Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé e yín ró nínú rẹ̀, ẹ máa se alágbára nínú ìgbàgbọ́, bí a ti ṣe kọ́ ọ yín, àti kí ẹ sì máa ṣàn bí omi pẹ̀lú ọpẹ́.
8 Ẹ máa kiyesii pé ẹnikẹ́ni kò fi ìmọ̀ àti ẹtan asan ko yín ní ìgbèkùn, èyí tí ó jẹmọ́ ìtàn ènìyàn bi ìpilẹ̀sẹ ẹ̀kọ́ ayé láìse ohun tí Kírísítì ti wí.
9 Nítorí nínú Kírísítì ni àti rí ẹ̀kún ìwà Ọlọ́run ní ipò ara,
10 ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kírísítì, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.
11 Nínú ẹni tí a kò fí ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní Ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kírísítì.
12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.