9 Nítorí nínú Kírísítì ni àti rí ẹ̀kún ìwà Ọlọ́run ní ipò ara,
10 ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kírísítì, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.
11 Nínú ẹni tí a kò fí ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní Ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kírísítì.
12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.
13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí o ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ni, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín;
14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn-án a mọ àgbélébùú;
15 Ó sì ti já àwọn aláṣẹ àìrí àti àwọn alágbára, ó ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn nínú rẹ̀.