2 Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lóké kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé.
3 Nítorí ẹ̀yín ti kú, a sì fi iyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kírísítì nínú Ọlọ́run.
4 Nígbà tí Kírísítì, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.
5 Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyìí jásí ìbọ̀rìsà.
6 Lórí àwọn wọ̀nyìí ni ìbínú Ọlọ́run ńbọ̀ wá.
7 Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apákan ayé yìí.
8 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyìí sílẹ̀: ìbínú, ìrúnú, àránkan, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín.