2 Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́;
3 Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣílẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kírísítì, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú:
4 Ẹ gbàdúrà pé kí èmí leè máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi.
5 Ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n ni tí bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ńbẹ̀ lóde, kí ẹ sì máa ra ìgbà padà.
6 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá òlúkulùlku ènìyàn lóhùn.
7 Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikíkú yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀ gbogbo bí nǹkan tirí nípa mi. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòótọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa:
8 Ẹni tí èmí ń rán sí yín ńitorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọ̀kàn yín nínú;