9 Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Ónísímù, arákùnrin olóòótọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.
10 Árísítákù, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Máàkù, ọmọ arábìnrin Bánábà (Nípaṣẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).
11 Àti Jésù, ẹni tí à ń pè ní Jọsítọ́sì, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbá ṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí já sí ìtùnú fún mi.
12 Épáfúrà, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àtiìránṣẹ́ Kírísítì kí í yín. Òun fí ìwàyájà gbàdúrà nígbà gbogbo fún-ún yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
13 Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣisẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodékíà, àti àwọn tí ó wà ní Hírápólì.
14 Lúùkù, aràkùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dẹ́mà ki í yín.
15 Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ńi Laodékíà, àti Nímífásì, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.