10 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin yín, ẹ bá a wí lẹ́ẹ̀kínní àti lẹ́ẹ̀kejì. Lẹ́yìn náà, ẹ má ṣe ní ohunkóhun íṣe pẹ̀lú rẹ̀.
11 Kí ó dá ọ lójú wí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti yapa, ó jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, ó sì dá ara rẹ̀ lẹ́ni.
12 Ní kété tí mo bá ti rán Àtémà tàbí Tíkíkù sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tòmíwá ní Níkópólì, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀.
13 Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Sénà agbẹjọ́rò àti Àpólò lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọn ní ohun gbogbo tí wọn nílò.
14 Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jìn sí iṣẹ́ rere kí wọn baà le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso.
15 Gbogbo àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ mi kí ọ. Bá mi kí àwọn tí ó fẹ́ wa nínú ìgbàgbọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.