1 Samsoni lọ sí Timna, ó rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia níbẹ̀.
2 Ó pada wálé wá sọ fún baba ati ìyá rẹ̀, ó ní, “Mo rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia ní Timna, ó wù mí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fẹ́ ẹ fún mi.”
3 Baba ati ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Ṣé kò sí obinrin mọ́ ninu gbogbo àwọn ìbátan rẹ tabi láàrin gbogbo àwọn eniyan wa ni o fi níláti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ará Filistia aláìkọlà ni?”Samsoni bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Ẹ ṣá fẹ́ ẹ fún mi nítorí ó wù mí pupọ.”
4 Ṣugbọn baba ati ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ní ọwọ́ OLUWA ninu, nítorí pé OLUWA ti ń wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Filistia nítorí pé, àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àkókò yìí.
5 Samsoni bá baba ati ìyá rẹ̀ lọ sí Timna ní ọjọ́ kan. Bí ó ti dé ibi ọgbà àjàrà àwọn ará Timna kan báyìí, ni ọ̀dọ́ kinniun kan bá bú mọ́ ọn.