Àwọn Adájọ́ 20 BM

Israẹli Múra Ogun

1 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa.

2 Gbogbo àwọn olórí láàrin àwọn eniyan náà jákèjádò ilẹ̀ Israẹli kó ara wọn jọ pẹlu ìjọ eniyan Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn, tí wọ́n sì ń lo idà, tí wọ́n kó ara wọn jọ níbẹ̀ tàwọn ti idà lọ́wọ́ wọn jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (400,000).

3 Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti kó ara wọn jọ ní Misipa.Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ ọmọ Lefi náà pé, “Sọ fún wa, báwo ni nǹkan burúkú yìí ti ṣe ṣẹlẹ̀?”

4 Ọmọ Lefi, ọkọ obinrin tí wọ́n pa, bá dáhùn pé, “Èmi ati obinrin mi ni a yà sí Gibea ní ilẹ̀ àwọn ará Bẹnjamini pé kí á sùn níbẹ̀.

5 Àwọn ọkunrin Gibea bá dìde lóru, wọ́n yí ilé tí mo wà po, wọ́n fẹ́ pa mí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá obinrin mi lòpọ̀ títí tí ó fi kú.

6 Mo bá gbé òkú rẹ̀, mo gé e lékìrí lékìrí, mo bá fi ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ Israẹli jákèjádò, nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti ṣe nǹkan burúkú ati ohun ìríra ní Israẹli.

7 Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gba ọ̀rọ̀ yí yẹ̀wò, kí ẹ sì mú ìmọ̀ràn yín wá lórí rẹ̀ nisinsinyii.”

8 Gbogbo àwọn eniyan náà bá fi ohùn ṣọ̀kan pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní pada sí àgọ́ rẹ̀ tabi ilé rẹ̀.

9 Ohun tí a óo ṣe nìyí, gègé ni a óo ṣẹ́ láti mọ àwọn tí yóo gbógun ti Gibea.

10 Ìdámẹ́wàá àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli yóo máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun, àwọn yòókù yóo lọ jẹ àwọn ará Gibea níyà fún ìwà burúkú tí wọ́n hù ní Israẹli yìí.”

11 Gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n gbógun ti ìlú náà.

12 Àwọn ọmọ Israẹli rán oníṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ Bẹnjamini, wọ́n ní, “Irú ìwà ìkà wo ni ẹ hù yìí?

13 Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí.

14 Àwọn ọmọ Bẹnjamini bá kó ara wọn jọ láti gbogbo ìlú ńláńlá, wọ́n wá sí Gibea láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

15 Àwọn ọmọ ogun tí àwọn ará Bẹnjamini kó jọ ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaata (26,000) àwọn ọkunrin tí wọn ń lo idà; láì ka àwọn tí wọn ń gbé Gibea tí àwọn náà kó ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin jọ.

16 Ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin tí wọn ń lo ọwọ́ òsì wà láàrin àwọn ọmọ ogun wọnyi. Wọ́n mọ kànnàkànnà ta, tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé wọ́n lè ta á mọ́ fọ́nrán òwú láì tàsé.

17 Láì ka àwọn tí àwọn ará Bẹnjamini náà kó jọ, àwọn ọmọ Israẹli kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) jagunjagun tí wọn ń lo idà jọ.

Israẹli Bá Ẹ̀yà Bẹnjamini Jagun

18 Àwọn ọmọ Israẹli gbéra lọ sí Bẹtẹli, wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun; ẹ̀yà tí yóo kọ́kọ́ gbógun ti ẹ̀yà Bẹnjamini.OLUWA dá wọn lóhùn pé ẹ̀yà Juda ni yóo kọ́kọ́ gbógun tì wọ́n.

19 Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ pàgọ́ sí òdìkejì Gibea,

20 wọ́n bá gbógun ti àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fi ìlú Gibea ṣe ojú ogun wọn.

21 Àwọn ará Bẹnjamini bá jáde sí wọn láti ìlú Gibea, wọ́n sì pa ọ̀kẹ́ kan (20,000) ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ọjọ́ náà.

22 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn.

23 Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?”OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.

24 Àwọn ọmọ Israẹli bá tún lọ gbógun ti àwọn ọmọ ogun Bẹnjamini ní ọjọ́ keji.

25 Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà.

26 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá lọ sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó wọ́n sọkún níbẹ̀ níwájú OLUWA, wọ́n gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú OLUWA.

27 Àwọn ọmọ Israẹli tún wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí pé àpótí majẹmu Ọlọrun wà ní Bẹtẹli ní àkókò náà.

28 Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?”OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”

29 Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea.

30 Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju.

31 Àwọn ará Bẹnjamini jáde sí wọn, àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí fi ọgbọ́n tàn wọ́n kúrò ní ìlú; àwọn ará Bẹnjamini tún bẹ̀rẹ̀ sí pa ninu àwọn ọmọ Israẹli bíi ti iṣaaju. Wọ́n pa wọ́n ní ojú òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹtẹli ati Gibea ati ninu pápá. Àwọn tí wọ́n pa ninu wọ́n tó ọgbọ̀n eniyan.

32 Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.”Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.”

33 Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba.

34 Ni ẹgbaarun (10,000) àṣàyàn àwọn jagunjagun ninu àwọn ọmọ Israẹli bá gbógun ti ìlú Gibea. Ogun náà gbóná gidigidi ṣugbọn àwọn ará Bẹnjamini kò mọ̀ pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí wọn.

35 OLUWA bá ṣẹgun àwọn ará Bẹnjamini fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbẹẹdọgbọn ó lé ọgọrun-un (25,100) eniyan ninu àwọn ará Bẹnjamini lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pa jẹ́ jagunjagun tí wọn ń lo idà.

Ìṣẹ́gun Israẹli

36 Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini.

37 Àwọn tí wọ́n ba ní ibùba yára jáde, wọ́n gbógun ti Gibea, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run.

38 Àmì tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn tí wọ́n ba ní ibùba ti jọ ṣe fún ara wọn ni pé, nígbà tí wọ́n bá rí i tí èéfín ńlá yọ sókè ní Gibea,

39 kí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ń sá lọ yipada, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ará Bẹnjamini ti pa bí ọgbọ̀n jagunjagun ninu àwọn Israẹli, wọ́n sì ti ń wí ninu ará wọn pé, “Dájúdájú a ti ṣẹgun wọn bíi ti àkọ́kọ́.”

40 Ṣugbọn nígbà tí èéfín tí àwọn ọmọ ogun Israẹli fi ṣe àmì bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láàrin ìlú, àwọn ará Bẹnjamini wo ẹ̀yìn, wọ́n rí i pé èéfín ti sọ, ó sì ti gba ìlú kan.

41 Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí wọn, ìdààmú sì bá àwọn ọmọ Bẹnjamini nítorí wọ́n rí i pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí.

42 Nítorí náà, wọ́n pada lẹ́yìn àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí ìhà aṣálẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ bà wọ́n, nítorí pé ààrin àwọn jagunjagun tí wọ́n yipada sí wọn, ati àwọn tí wọn ń jáde bọ̀ láti inú ìlú ni wọ́n bọ́ sí.

43 Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láì dáwọ́ dúró bí wọn ti ń lé wọn lọ. Wọ́n pa wọ́n láti Nohahi títí dé iwájú ìlà oòrùn Gibea.

44 Ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) ninu àwọn akikanju ará Bẹnjamini ni àwọn ọmọ Israẹli pa.

45 Wọ́n bá yipada, wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ tí ó lọ sí ibi àpáta Rimoni, àwọn ọmọ Israẹli sì tún pa ẹẹdẹgbaata (5,000) ninu wọn ní ojú ọ̀nà. Wọ́n ń lé wọn lọ tete títí dé Gidomu, wọ́n sì tún pa ẹgbaa (2,000) eniyan ninu wọn.

46 Gbogbo àwọn tí wọ́n kú ninu àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹẹdẹgbaata (25,000); gbogbo wọ́n jẹ́ akikanju jagunjagun tí ń lo idà.

47 Ṣugbọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu wọn sá lọ sí apá aṣálẹ̀, síbi àpáta Rimoni, wọ́n sì ń gbé inú àpáta Rimoni náà fún oṣù mẹrin.

48 Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí àwọn ará Bẹnjamini, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá fojú kàn, ati eniyan ati ẹranko. Gbogbo ìlú wọn tí wọ́n rí ni wọ́n sì sun níná.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21