1 Ní àkókò kan, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli, ati pé, ní àkókò náà, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tí wọn yóo gbà, tí wọn yóo sì máa gbé, nítorí pé, títí di àkókò yìí wọn kò tíì fún wọn ní ilẹ̀ kankan láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli.
2 Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Dani rán akikanju marun-un láàrin àwọn eniyan wọn, láti ìlú Sora ati Eṣitaolu, kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n wí fún àwọn amí náà pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì yẹ ilẹ̀ náà wò.” Wọ́n bá gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè ti Efuraimu. Nígbà tí wọ́n dé ilé Mika, wọ́n wọ̀ sibẹ.
3 Nígbà tí wọ́n wà ní ilé Mika, wọ́n ṣàkíyèsí bí ọdọmọkunrin tí ó wà ní ilé Mika ṣe ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì mọ̀ pé ọmọ Lefi ni. Wọ́n bá bi í pé, “Ta ló mú ọ wá síhìn-ín? Kí ni ò ń ṣe níhìn-ín? Kí sì ni iṣẹ́ rẹ?”
4 Ó dá wọn lóhùn pé, “Mika ti bá mi ṣètò, ó ti gbà mí gẹ́gẹ́ bí alufaa rẹ̀.”
5 Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, bá wa wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun, kí á lè mọ̀ bóyá ìrìn àjò tí à ń lọ yìí yóo yọrí sí rere.”
6 Alufaa náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní alaafia, Ọlọrun fọwọ́ sí ìrìn àjò tí ẹ̀ ń lọ.”
7 Àwọn ọkunrin marun-un náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n wá sí Laiṣi, wọ́n sì rí àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀ bí wọ́n ti ń gbé ní àìléwu gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Sidoni tií máa ṣe. Wọ́n ń gbé pọ̀ ní alaafia, kò sí ìjà láàrin wọn, wọ́n ní ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ní ọrọ̀. Wọ́n rí i bí wọ́n ti jìnnà sí ibi tí àwọn ará Sidoni wà tó, ati pé wọn kò bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀ ní gbogbo àyíká wọn.