1 Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún meje.
2 Àwọn ará Midiani lágbára ju àwọn ọmọ Israẹli lọ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli fi ṣe ibi tí wọn ń sápamọ́ sí lórí àwọn òkè, ninu ihò àpáta, ati ibi ààbò mìíràn ninu òkè.
3 Nítorí pé, nígbàkúùgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá gbin ohun ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani ati àwọn ará Amaleki ati àwọn kan láti inú aṣálẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, a máa kó ara wọn jọ, wọn a lọ ṣígun bá àwọn ọmọ Israẹli.
4 Wọn a gbógun tì wọ́n, wọn a sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà jẹ́ títí dé agbègbè Gasa. Wọn kì í fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ rárá ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi aguntan tabi mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan sílẹ̀.
5 Nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀, tilé-tilé ni wọ́n wá. Wọn á kó àwọn àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́, wọn á sì bo àwọn ọmọ Israẹli bí eṣú. Àwọn ati ràkúnmí wọn kò níye, nítorí náà nígbà tí wọ́n bá dé, wọn á jẹ gbogbo ilẹ̀ náà ní àjẹrun.
6 Àwọn ọmọ Israẹli di ẹni ilẹ̀ patapata, nítorí àwọn ará Midiani. Nítorí náà, wọ́n ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́.