15 Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́,ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó.
16 Ó fẹnu mi gbolẹ̀,títí yangí fi ká mi léyín;ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku
17 Ọkàn mi kò ní alaafia,mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀.
18 Nítorí náà, mo wí pé,“Ògo mi ti tán,ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.”
19 Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,ati ìrora ọkàn mi!
20 Mò ń ranti nígbà gbogbo,ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì.
21 Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan,mo sì ní ìrètí.