1 Ẹ wò bí OLUWA ti fi ibinufi ìkùukùu bo Sioni mọ́lẹ̀.Ó ti wọ́ ògo Israẹli luláti òkè ọ̀run sórí ilẹ̀ ayé;kò tilẹ̀ ranti àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.
2 OLUWA ti pa gbogbo ibùgbé Jakọbu run láìsí àánú.Ó ti fi ibinu wó ibi ààbò Juda lulẹ̀.Ó ti rẹ ìjọba ati àwọn aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀,ó fi àbùkù kàn wọ́n.
3 Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,pa àwọn alágbára Israẹli;ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́,nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n.Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná,ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run.
4 Ó kẹ́ ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá,ó múra bí aninilára.Gbogbo ògo wa ló parun lójú wa,ó sì tú ibinu rẹ̀ jáde bí iná, ninu àgọ́ Sioni.
5 OLUWA ṣe bí ọ̀tá,ó ti pa Israẹli run.Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run,ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpàó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ.
6 Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀,bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko.Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run.OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni.Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,kọ ọba ati alufaa sílẹ̀.
7 OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́,ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́;wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWAgẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀.
8 OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀.Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n,kò sì rowọ́ láti parun.Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́,wọ́n sì di àlàpà papọ̀.
9 Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì, wọ́n ti wọlẹ̀;ó ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè;ọba rẹ̀ ati àwọn olórí rẹ̀ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn;òfin kò sí mọ́, àwọn wolii rẹ̀ kò sì ríran láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.
10 Àwọn àgbààgbà Sioni jókòó lórí ilẹ̀, wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́,wọ́n ku eruku sórí,wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.Àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu doríkodò.
11 Ẹkún sísun ti sọ ojú mi di bàìbàì,ìdààmú bá ọkàn mi;ìbànújẹ́ sì mú kí ó rẹ̀wẹ̀sìnítorí ìparun àwọn eniyan mi,nítorí pé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ati àwọn ọmọ ọwọ́ ń dákú lójú pópó láàrin ìlú.
12 Bí wọ́n ti ń dákú láàrin ìlú,bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́,tí wọ́n sì ń kú lọ lẹ́yìn ìyá wọn,wọ́n ń sọkún sí àwọn ìyá wọn pé:“Ebi ń pa wá, òùngbẹ sì ń gbẹ wá.”
13 Kí ni mo lè sọ nípa rẹ,kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu?Kí ni mo lè fi wé ọ,kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni?Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò;ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò?
14 Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ;wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́,kí wọ́n lè dá ire rẹ pada,ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ.
15 Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí,wọ́n ń pòṣé,wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu.Wọ́n ń sọ pé:“Ṣé ìlú yìí ni à ń pè níìlú tí ó lẹ́wà jùlọ,tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?”
16 Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ọ́ ṣẹ̀sín,wọ́n ń pòṣé,wọ́n ń fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.Wọ́n ń wí pé:“A ti pa á run!Ọjọ́ tí a tí ń retí nìyí;ọwọ́ wa ti tẹ Jerusalẹmu wàyí!A ti rí ohun tí à ń wá!”
17 OLUWA ti ṣe bí ó ti pinnu,ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ,bí ó ti sọ ní ìgbà àtijọ́.Ó ti wó ọ lulẹ̀ láìṣàánú rẹ;ó ti jẹ́ kí ọ̀tá yọ̀ ọ́,ó ti fún àwọn ọ̀tá rẹ ni agbára kún agbára.
18 Ẹ kígbe sí OLUWA,ẹ̀yin ará Sioni!Ẹ jẹ́ kí omi máa dà lójú yín pòròpòrò tọ̀sán-tòru;ẹ má sinmi,ẹ má sì jẹ́ kí oorun kùn yín.
19 Ẹ dìde, ẹ kígbe lálẹ́,ní àkókò tí àwọn aṣọ́de ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́!Ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín jáde bí omi níwájú OLUWA!Ẹ gbé ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sókè sí i,nítorí ẹ̀mí àwọn ọmọ yín tí ebi ń pa kú lọ ní gbogbo ìkóríta.
20 Wò ó! OLUWA,ṣe akiyesi ohun tí ń ṣẹlẹ̀!Wo àwọn tí ò ń ṣe irú èyí sí!Ṣé ó yẹ kí àwọn obinrin máa jẹ ọmọ wọn?Ọmọ ọwọ́ tí wọn ń tọ́jú!Ṣé ó yẹ kí á pa alufaa ati wolii, ní ibi mímọ́ OLUWA?
21 Àtàwọn ọ̀dọ́, àtàwọn arúgbówọ́n kú kalẹ̀ lọ lójú pópó,àtàwọn ọdọmọbinrin, àtàwọn ọdọmọkunrin mi,gbogbo wọn ni idà ti pa.Ní ọjọ́ ibinu rẹ ni o pa wọ́n,o pa wọ́n ní ìpakúpa láìṣàánú wọn.
22 O pe àwọn ọ̀tá mi jọ sí mibí ẹni peniyan síbi àjọ̀dún;kò sì sí ẹni tí ó yèní ọjọ́ ibinu rẹ, OLUWA.Ọ̀tá mi pa àwọn ọmọ mi run,àwọn tí mo tọ́, tí mo sì fẹ́ràn.