19 Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,ati ìrora ọkàn mi!
20 Mò ń ranti nígbà gbogbo,ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì.
21 Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan,mo sì ní ìrètí.
22 Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun,àánú rẹ̀ kò sì lópin;
23 ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀,òtítọ́ rẹ̀ pọ̀.
24 Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi,nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”
25 OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é,tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.