25 OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é,tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.
26 Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA.
27 Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe.
28 Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye,nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn.
29 Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀,bóyá ìrètí lè tún wà fún un.
30 Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí,kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án.
31 Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae.