32 Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa,yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu,gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
33 Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan láratabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí.
34 OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé,
35 kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo,
36 tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo.
37 Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀,láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i?
38 Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògoni rere ati burúkú ti ń jáde?