42 “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun,ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá.
43 “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù,ò ń lépa wa,o sì ń pa wá láì ṣàánú wa.
44 O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ,tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ.
45 O ti sọ wá di ààtànati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan.
46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára.
47 Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa.
48 Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi,nítorí ìparun àwọn eniyan mi.