8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́,sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi.
9 Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi,ó mú kí ọ̀nà mí wọ́.
10 Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀,ó lúgọ bíi kinniun,
11 Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi,ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,ó sì ti sọ mí di alailẹnikan.
12 Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀,ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
13 Ó mú gbogbo ọfàtí ó wà ninu apó rẹ̀ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn.
14 Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́lọ́dọ̀ gbogbo eniyan,ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru.