18 Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro;tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀.
19 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé,ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran.
20 Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata?Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́?
21 Mú wa pada sọ́dọ̀ ara rẹ, OLUWA,kí á lè pada sí ipò wa.Mú àwọn ọjọ́ àtijọ́ wa pada.
22 Ṣé o ti kọ̀ wá sílẹ̀ patapata ni?Àbí o sì tún ń bínú sí wa, inú rẹ kò tíì rọ̀?