6 A ti fa ara wa kalẹ̀ fún àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Asirianítorí oúnjẹ tí a óo jẹ.
7 Àwọn baba wa ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àwọn sì ti kú,ṣugbọn àwa ni à ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8 Àwọn ẹrú ní ń jọba lé wa lórí,kò sì sí ẹni tí yóo gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9 Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ,nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀.
10 Awọ ara wa gbóná bí iná ààrò,nítorí ìyàn tí ó mú lọpọlọpọ.
11 Tipátipá ni wọ́n fi ń bá àwọn obinrin lòpọ̀ ní Sioni,ati àwọn ọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin ní Juda.
12 Wọ́n fi okùn so ọwọ́ àwọn olórí rọ̀,wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà.