7 Àwọn baba wa ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àwọn sì ti kú,ṣugbọn àwa ni à ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8 Àwọn ẹrú ní ń jọba lé wa lórí,kò sì sí ẹni tí yóo gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9 Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ,nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀.
10 Awọ ara wa gbóná bí iná ààrò,nítorí ìyàn tí ó mú lọpọlọpọ.
11 Tipátipá ni wọ́n fi ń bá àwọn obinrin lòpọ̀ ní Sioni,ati àwọn ọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin ní Juda.
12 Wọ́n fi okùn so ọwọ́ àwọn olórí rọ̀,wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà.
13 Wọ́n fi ipá mú àwọn ọdọmọkunrin pé kí wọn máa lọ ọlọ,àwọn ọmọde ru igi títí àárẹ̀ mú wọn!