1 Nígbà tí Modekai gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Ó fi àkísà ati eérú bo ara rẹ̀. Ó kígbe lọ sí ààrin ìlú, ó ń pohùnréré ẹkún.
2 Ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn kò wọlé nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wọ àkísà wọ inú ààfin.
3 Ní gbogbo agbègbè ati káàkiri ibi tí òfin ati àṣẹ ọba dé, ni àwọn Juu tí ń ṣọ̀fọ̀ tí wọn ń gbààwẹ̀ tẹkúntẹkún. Ọpọlọpọ wọn da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n sì da eérú sára.
4 Nígbà tí àwọn iranṣẹbinrin Ẹsita ati àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ sọ fún un nípa Modekai, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó kó aṣọ ranṣẹ sí i, kí ó lè pààrọ̀ àkísà rẹ̀, ṣugbọn Modekai kọ̀ wọ́n.
5 Ẹsita bá pe Hataki, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí ọba ti yàn láti máa ṣe iranṣẹ fún un. Ó pàṣẹ fún un pé kí ó lọ bá Modekai kí ó bèèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó fà á.