1 Nígbà tí ó yá, tí ibinu ọba rọlẹ̀, ó ranti ohun tí Faṣiti ṣe, ati àwọn àṣẹ tí òun pa nípa rẹ̀.
2 Àwọn iranṣẹ ọba tí wọ́n súnmọ́ ọn tímọ́tímọ́ bá sọ fún un pé,
3 “Jẹ́ kí á wá àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà fún ọba, kí á yan àwọn eniyan ní gbogbo ìgbèríko ìjọba rẹ̀ láti ṣa àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà wá sí ibi tí àwọn ayaba ń gbé ní ààfin, ní Susa, tíí ṣe olú ìlú, kí wọ́n wà lábẹ́ ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, tíí ṣe olùtọ́jú àwọn ayaba, kí á sì fún wọn ní àwọn ohun ìpara,
4 kí wundia tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn jù sì jẹ́ ayaba dípò Faṣiti.” Ìmọ̀ràn yìí dùn mọ́ ọba ninu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.
5 Ọkunrin kan, ará Juda láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini wà ní ààfin Susa, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Modekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi.
6 Ó wà lára àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lẹ́rú láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ Babiloni pẹlu Jekonaya, ọba Juda.
7 Modekai ń tọ́ ọmọbinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadasa tabi Ẹsita. Ọmọ yìí jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ṣugbọn kò ní òbí mọ́. Ọmọ náà lẹ́wà gidigidi. Modekai mú un sọ́dọ̀ bí ọmọ ara rẹ̀, lẹ́yìn tí baba ati ìyá rẹ̀ ti kú.
8 Nígbà tí ọba pàṣẹ, tí wọ́n kéde rẹ̀, tí wọ́n sì mú ọpọlọpọ wundia wá sí ààfin, ní Susa, ní abẹ́ ìtọ́jú Hegai, tí ń tọ́jú àwọn ayaba, Ẹsita wà pẹlu wọn ní ààfin ní abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.
9 Ẹsita wú Hegai lórí, inú rẹ̀ dùn sí i pupọ. Ó fún un ní nǹkan ìpara ati oúnjẹ kíákíá. Ó tún fún un ní àwọn ọmọbinrin meje ninu àwọn iranṣẹbinrin tí wọ́n wà ní ààfin. Ó fún Ẹsita ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ní ibi tí ó dára jùlọ ní ibi tí àwọn ayaba ń gbé.
10 Ẹsita kò sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá, tabi ìdílé rẹ̀, fún ẹnikẹ́ni nítorí pé Modekai ti kìlọ̀ fún un pé kí ó má ṣe sọ nǹkankan nípa rẹ̀.
11 Lojoojumọ ni Modekai máa ń rìn sókè sódò níwájú àgbàlá ibi tí àwọn ayaba ń gbé, láti bèèrè alaafia Ẹsita, ati bí ó ti ń ṣe sí.
12 Kí wundia kankan tó lè lọ rí ọba, ó gbọdọ̀ kọ́ wà ninu ilé fún oṣù mejila, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn obinrin wọn. Oṣù mẹfa ni wọ́n fi ń kun òróró ati òjíá, wọn á sì fi oṣù mẹfa kun òróró olóòórùn dídùn ati ìpara àwọn obinrin.
13 Nígbà tí wundia kan bá ń lọ siwaju ọba, lẹ́yìn tí ó ba ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó yẹ, ó lè gba ohunkohun tí ó bá fẹ́ mú lọ láti ilé àwọn ayaba.
14 Yóo lọ sibẹ ní alẹ́, ní òwúrọ̀ yóo pada wá sí ilé keji tí àwọn ayaba ń lò, tí ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi, ìwẹ̀fà tí ó ń tọ́jú àwọn obinrin ọba. Kò tún ní pada lọ rí ọba mọ́, àfi bí inú ọba bá dùn sí i tí ó sì ranṣẹ pè é.
15 Nígbà tí ó tó àkókò fún Ẹsita, ọmọ Abihaili ẹ̀gbọ́n Modekai, láti lọ rí ọba, Ẹsita kò bèèrè nǹkankan ju ohun tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba tí ń tọ́jú àwọn ayaba, sọ fún un pé kí ó mú lọ. Ẹsita rí ojurere lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n rí i.
16 Wọ́n mú Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba Ahasu-erusi ní ààfin rẹ̀ ní oṣù Tebeti, tíí ṣe oṣù kẹwaa, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀.
17 Ọba fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo àwọn obinrin yòókù lọ, ó sì rí ojurere ọba ju gbogbo àwọn wundia yòókù lọ. Ọba gbé adé lé e lórí, ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣiti.
18 Ọba bá se àsè ńlá fún àwọn olóyè ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ nítorí Ẹsita. Ó fún gbogbo eniyan ní ìsinmi, ó sì fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn.
19 Nígbà tí àwọn wundia péjọ ní ẹẹkeji, Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin.
20 Ṣugbọn Ẹsita kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀yà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Modekai ti pàṣẹ fún un, nítorí ó gbọ́ràn sí Modekai lẹ́nu, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nígbà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.
21 Ní àkókò náà, nígbà tí Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin, meji ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà: Bigitana ati Tereṣi, ń bínú sí ọba, wọ́n sì ń dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba.
22 Ṣugbọn Modekai gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ fún Ẹsita, ayaba, Ẹsita bá tètè lọ sọ fún ọba pé Modekai ni ó gbọ́ nípa ète náà tí ó sọ fún òun.
23 Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì rí i pé òtítọ́ ni, wọ́n so àwọn ọlọ̀tẹ̀ mejeeji náà kọ́ sórí igi. Wọ́n sì kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìwé ìtàn ìjọba níwájú ọba.