6 Bí wọn tí ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita léèrè pé, “Kí ni ìbéèrè rẹ Ẹsita, a óo ṣe é fún ọ, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ ni a óo jẹ́ kí ó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ títí dé ìdajì ìjọba mi.”
7 Ẹsita bá dáhùn pé, “Ìbéèrè ati ẹ̀bẹ̀ mi ni pé,
8 bí inú kabiyesi bá dùn sí mi láti ṣe ohun tí mò ń fẹ́, ati láti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, kí kabiyesi ati Hamani wá síbi àsè tí n óo sè fún wọn ní ọ̀la. Nígbà náà ni n óo sọ ohun tí ó wà ní ọkàn mi.”
9 Hamani jáde pẹlu ayọ̀ ńlá, ati ìdùnnú. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Modekai ní ẹnu ọ̀nà ààfin, tí kò tilẹ̀ mira rárá tabi kí ó wárìrì, inú bí i sí Modekai.
10 Ṣugbọn Hamani pa á mọ́ra, ó lọ sí ilé rẹ̀. Ó pe gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ tí ń jẹ́ Sereṣi,
11 ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu fún wọn bí ọrọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó, iye àwọn ọmọ rẹ̀, bí ọba ṣe gbé e ga ju gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn olórí yòókù lọ.
12 Hamani tún fi kún un pé “Ayaba Ẹsita kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá ọba wá sí ibi àsè rẹ̀, àfi èmi nìkan. Ó sì ti tún pe èmi ati ọba sí àsè mìíràn ní ọ̀la.