22 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn.
23 Àwọn Juu gbà láti máa ṣe bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ati bí àṣẹ Modekai.
24 Nítorí Hamani, ọmọ Hamedata, láti ìran Agagi, ọ̀tá àwọn Juu ti pète láti pa àwọn Juu run. Ó ti ṣẹ́ gègé, tí wọn ń pè ní Purimu, láti mọ ọjọ́ tí yóo pa àwọn Juu run patapata.
25 Ṣugbọn nígbà tí Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba, ọba kọ̀wé àṣẹ tí ó mú kí ìpinnu burúkú tí Hamani ní sí àwọn Juu pada sí orí òun tìkararẹ̀, a sì so òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sórí igi.
26 Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ náà ní Purimu gẹ́gẹ́ bí orúkọ Purimu, gègé tí Hamani ṣẹ́. Nítorí ìwé tí Modekai kọ ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn,
27 ni àwọn Juu fi sọ ọ́ di òfin fún ara wọn, ati fún arọmọdọmọ wọn, ati fún àwọn tí wọ́n bá di Juu, pé ní àkókò rẹ̀, ní ọdọọdún, ọjọ́ mejeeji yìí gbọdọ̀ jẹ́ ọjọ́ àsè, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Modekai,
28 ati pé kí wọ́n máa ranti àwọn ọjọ́ wọnyi, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìrandíran, ní gbogbo ìdílé, ní gbogbo agbègbè ati ìlú. Àwọn ọjọ́ Purimu wọnyi kò gbọdọ̀ yẹ̀ láàrin àwọn Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìrántí wọn kò gbọdọ̀ parun láàrin arọmọdọmọ wọn.