28 ati pé kí wọ́n máa ranti àwọn ọjọ́ wọnyi, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìrandíran, ní gbogbo ìdílé, ní gbogbo agbègbè ati ìlú. Àwọn ọjọ́ Purimu wọnyi kò gbọdọ̀ yẹ̀ láàrin àwọn Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìrántí wọn kò gbọdọ̀ parun láàrin arọmọdọmọ wọn.
29 Ẹsita Ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Modekai, tíí ṣe Juu kọ ìwé láti fi ìdí ìwé keji nípa Purimu múlẹ̀.
30 Wọ́n kọ ìwé sí gbogbo àwọn Juu ní gbogbo agbègbè mẹtẹẹtadinlaadoje (127) tí ó wà ninu ìjọba Ahasu-erusi. Ìwé náà kún fún ọ̀rọ̀ alaafia ati òtítọ́,
31 pé wọn kò gbọdọ̀ gbàgbé láti máa pa àwọn ọjọ́ Purimu mọ́ ní àkókò wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Modekai ati Ẹsita Ayaba pa fún àwọn Juu, ati irú ìlànà tí wọ́n là sílẹ̀ fún ara wọn ati arọmọdọmọ wọn, nípa ààwẹ̀ ati ẹkún wọn.
32 Àṣẹ tí Ẹsita pa fi ìdí àjọ̀dún Purimu múlẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀.