5 Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí.
6 Ó dúró, ó wọn ayé;Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì;àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká,àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀.Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀.
7 Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu,àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì.
8 OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni,àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí,tabi òkun ni ò ń bá bínú,nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ,tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ?
9 Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun,tí o fi ọfà lé ọsán ọrun;tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé.
10 Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ,wọ́n wárìrì;àgbàrá omi wọ́ kọjá;ibú òkun pariwo,ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
11 Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn,nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò,tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà,bí wọ́n ti ń fò lọ.