Sakaraya 10 BM

OLUWA Ṣèlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 Ẹ bèèrè òjò lọ́wọ́ OLUWA ní àkókò rẹ̀, àní lọ́wọ́ OLUWA tí ó dá ìṣúdẹ̀dẹ̀ òjò; Òun ló ń fún eniyan ní ọ̀wààrà òjò, tí àwọn ohun ọ̀gbìn fi ń tutù yọ̀yọ̀.

2 Ìsọkúsọ ni àwọn ère ń sọ, àwọn aríran ń ríran èké; àwọn tí ń lá àlá ń rọ́ àlá irọ́, wọ́n sì ń tu àwọn eniyan ninu lórí òfo. Nítorí náà ni àwọn eniyan fi ń rìn káàkiri bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.

3 OLUWA ní, “Inú mi ru sí àwọn olùṣọ́-aguntan, n óo sì fìyà jẹ àwọn alákòóso. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń tọ́jú agbo mi, àní àwọn eniyan Juda, wọn yóo sì dàbí ẹṣin alágbára lójú ogun.

4 Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi.

5 Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin.

6 “N óo sọ ilé Juda di alágbára,n óo sì gba ilé Josẹfu là.N óo mú wọn pada,nítorí àánú wọn ń ṣe mí,wọn yóo dàbí ẹni pé n kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ rí;nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn,n óo sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ wọn.

7 Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára,inú wọn yóo sì dùnbí inú ẹni tí ó mu ọtí waini.Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i,inú wọn yóo dùn,ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA.

8 “N óo ṣẹ́wọ́ sí wọn,n óo sì kó wọn jọ sinu ilé.Mo ti rà wọ́n pada,nítorí náà wọn yóo tún pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn kásí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà.Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè,wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn.

10 N óo kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn láti ilẹ̀ Ijipti wá,n óo kó wọn jọ láti ilẹ̀ Asiria;n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Lẹbanoni,wọn óo kún ilẹ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ààyè mọ́.

11 Wọn óo la òkun Ijipti kọjá,ìgbì rẹ̀ yóo sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.Odò Naili yóo gbẹ kanlẹ̀,a óo rẹ ìgbéraga ilẹ̀ Asiria sílẹ̀,agbára óo sì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.

12 N óo sọ wọ́n di alágbára ninu èmi OLUWA,wọn yóo sì máa ṣògo ninu orúkọ mi.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14