Sakaraya 10:4-10 BM

4 Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi.

5 Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin.

6 “N óo sọ ilé Juda di alágbára,n óo sì gba ilé Josẹfu là.N óo mú wọn pada,nítorí àánú wọn ń ṣe mí,wọn yóo dàbí ẹni pé n kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ rí;nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn,n óo sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ wọn.

7 Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára,inú wọn yóo sì dùnbí inú ẹni tí ó mu ọtí waini.Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i,inú wọn yóo dùn,ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA.

8 “N óo ṣẹ́wọ́ sí wọn,n óo sì kó wọn jọ sinu ilé.Mo ti rà wọ́n pada,nítorí náà wọn yóo tún pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn kásí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà.Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè,wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn.

10 N óo kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn láti ilẹ̀ Ijipti wá,n óo kó wọn jọ láti ilẹ̀ Asiria;n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Lẹbanoni,wọn óo kún ilẹ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ààyè mọ́.