1 Ṣílẹ̀kùn rẹ, ìwọ ilẹ̀ Lẹbanonikí iná lè jó àwọn igi kedari rẹ!
2 Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi Sipirẹsi,nítorí igi kedari ti ṣubú,àwọn igi ológo ti parun.Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi oaku ní Baṣani,nítorí pé, a ti gé àwọn igi igbó dídí Baṣani lulẹ̀!
3 Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran,nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́.Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù,nítorí igbó tí wọn ń gbélẹ́bàá odò Jọdani ti parun!
4 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ọlọrun mi sọ; ó ní, “Fi ara rẹ sí ipò olùṣọ́-aguntan tí ó da àwọn ẹran rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n.
5 Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.”