3 Joṣua dúró níwájú angẹli Ọlọrun, pẹlu aṣọ tí ó dọ̀tí ní ọrùn rẹ̀.
4 Angẹli náà bá sọ fún àwọn tí wọ́n dúró tì í pé, “Ẹ bọ́ aṣọ tí ó dọ̀tí yìí kúrò lọ́rùn rẹ̀.” Ó bá sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò, n óo sì fi aṣọ tí ó lẹ́wà wọ̀ ọ́.”
5 Ó bá pàṣẹ pé, “Ẹ fi aṣọ mímọ́ wé e lórí.” Wọ́n bá fi aṣọ mímọ́ wé e lórí, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, angẹli OLUWA sì dúró tì í.
6 Angẹli náà kìlọ̀ fún Joṣua pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní,
7 “Bí o bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, o óo di alákòóso ilé mi ati àwọn àgbàlá rẹ̀. N óo sì fún ọ ní ipò láàrin àwọn tí wọ́n dúró wọnyi.
8 Gbọ́ nisinsinyii, ìwọ Joṣua, olórí alufaa, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin alufaa alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin ni àmì ohun rere tí ń bọ̀, pé n óo mú iranṣẹ mi wá, tí a pè ní Ẹ̀ka.
9 Wò ó! Nítorí mo gbé òkúta kan tí ó ní ojú meje siwaju Joṣua, n óo sì kọ àkọlé kan sórí rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ṣoṣo ni n óo mú ẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ yìí kúrò.