1 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn.
2 Ó bi mí pé kí ni mo rí.Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje.
3 Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.”
4 Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?”
5 Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.”
6 Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi.